Friday 26 July 2019

SEYI MAKINDE foruko awon komisanna ranse sile asofin -bee lo tun yan igbimo ti yoo gb’oro awon T’AJIMOBI da duro lenu ise wo

Yanju Adegboyega
SEYI MAKINDE foruko awon komisanna ranse sile asofin
-bee lo tun yan igbimo ti yoo gb’oro awon T’AJIMOBI da duro lenu ise wo
Lati le je ki ise ilu to gbe lowo rorun fun un, Gomina ipinle Oyo, Onimo-ero Seyi Makinde ti fi oruko awon eeyan merinla ranse sile igbimo asofin ipinle naa lati sayewo finni-finni fun won. Lara awon to foruko won ranse la ti ri Amofin Adeniyi Farinto; Ogbeni Adeniyi Olabode Adebisi; Onarebu Muyiwa Jacob Ojekunle; Ojogbon Oyewo Oyelowo; Amofin Seun Asamu; Amofin Lasunkanmi Ojeleye; Ogbeni Rahmon Abiodun Abdulraheem ati Oloye Bayo Lawal.
Awon to ku ni Onarebu Funmilayo Orisadeyi to je obinrin kan soso laarin won, Dokita Bashir Abiodun Bello; Onarebu Wasiu Olatunbosun; Ojogbon Daud Sangodoyin; Ogbeni Akinola Ojo ati Onarebu Kehinde Ayoola to ti figba kan je abenugan kile igbimo asofin ipinle Oyo lasiko isejoba Alaaji Lam Adesina.
Ewe, Gomina Seyi Makinde ti sagbekale igbimo eleni mejila kan ti yoo sagbeyewo ilana ti gomina tele, Sineto Abiola Ajimobi gba lati dawon eeyan kan duro lenu ise ijoba laarin odun 2011 si 2019. Gege baa se gbo, opo awon eeyan lo ti n ko’we ehonu ranse sijoba lat’igba ti Makinde ti depo ase pe, nise nijoba Ajimobi kan mo on mo fi iwa etaanu da won duro lenu ise ni.
Ni bayii, ijoba ti wa ke sawon eeyan ti oro ohun kan lati ko iwe ranse si yara ketadinlogbon nileese to n ri soro awon osise ijoba to wa ni sekiteriati ko to di ojo monde ojo karun-un osu kejo.

Friday 19 July 2019

Egbe omo bibi ile Ibadan gba MAKINDE nimoran lori siso egbin d’oro


Egbe omo bibi ile Ibadan gba MAKINDE nimoran lori siso egbin d’oro
Yanju Adegboyega
Bi ijoba ipinle Oyo labe akoso Onimo-ero Seyi Makinde se se agbekale ile-ejo alagbeeka lori imototo ayika, egbe omo bibi ile Ibadan, Central Council of Ibadan Indigenes, CCII ti gba ijoba nimoran lati sise lori siso egbin di oro, eyi to je okan lara ileri to se lasiko ipolongo ibo to koja.
Aare egbe CCII, Oloye Yemi Soladoye lo pe ipe ohun nibi ipade kan to waye lori ona ti ko ba ofin mu tawon eeyan fi n pa egbin mo nipinle Oyo. O woye pe, tijoba ba seto siso egbin d’oro. Nise lo ye ki won maa sanwo fawon to n da egbin nu, eyi ti won fi tun n gb’owo lowo won. Soladoye wa ro ijoba ipinle Oyo lati tete bere ise lori ibudo ti won ti n so egbin d’owo to wa laduugbo Orita Aperin niluu Ibadan, nitori ti won ti paa ti fun igba pipe.
Olori osise oba nipinle Oyo, Alaaja Ololade Hamdalat Agboola to se kokaari ipade ohun war o gbogbo awon to wa nibe lati tan ihinrere pi pa egbin mo lona ti ko fin ii fa wahala siluu.