Thursday 18 October 2018

O ma se o! Ose keji leyin iku BABA SALA, AJIMAJASAN naa tun ku

O ma se o!
Ose keji leyin iku BABA SALA, AJIMAJASAN naa ku
Yanju Adegboyega
Adanu nla mi-in tun sele sawon egbe osere tiata lorileede yii pelu bi okan pataki ninu awon agba osere ori-itage, pelu bi gbajumo osere alawada mi-in, Alagba Ola Omonitan, eni ti gbogbo awon ololufe ere tiata tun mo si “Ajimajasan tabi Baba no regret” naa tun se ku. Gege baa se gbo, ojo tosidee ose to koja yii ni okunrin gbajumo alawada ohun jade laye leni odun mejilelogorin.
Akoroyin wa gbo pe, okunrin naa ti n saisan fun igba die bayii, eyi to mu ki won gbee lo sileewosan ekose isegun Orita Mefa, UCH ni bi ose meloo seyin. Enikan to ba wa soro nileewosan UCH soo di mimo pe, lasiko ayewo tawon dokita se fun Ajimajasan ni won sakiyesi pe okan re tobi ju bo se ye lo, bee ni opa-eyin n dun un pelu arun jejere prostate cancer, eyi to mu ki won ti sise-abe fun un ri. Ohun to si seni laanu ni pe, won lo le sise-abe fun un mo rara nitori ojo-ori re ati pe ara re ko le gbaa duro.
Akoroyin wa gbo pe, dokita to n toju re lo si gbawon molebi re niyanju lati maa gbee lo sile pelu ileri lati wa maa toju re nile. Koda, ojo monde ose to lo ohun ni won se gbee kuro nileewosan, ko to di po ku lojo tosidee.
Gbogbo awon eeyan to ba ti gbonju niwon odun 1970 si 1980 yoo ranti Ola Omonitan daadaa pelu ere alawada re lori telifisan WNBC/WNTV. Koda, kaakiri ile Yoruba atawon ipinle bii Kwara ati Kogi ni won ti mo on bi eni m’owo niwon odun 1956 si 1959 pelu awon osere bii Duro Ladipo, Kola Ogunmola, Ayinla Olumegbon, Akin Ogungbe atawon mi-in bii Baba Sala.
Gege bo se wi ninu iforowero kan to se ri, pe iya agba oun lo maa fun oun lawon ere toun n se loju oorun. Ojo-ori re kere pupo nigba ti baba re ku, eyi to je ki wahala itoju re bo sowo iya re. Iya re ko ko iha to daa si ero re lati je osere, nigba ti apa re ko ka ati ran nileewe, o gbaa nimoran lati lo ko’se owo. Eyi to mu ko lo maa ko ise awon to n se aga igbalode, furniture laduugbo Oke-Ado.
Sugbon, bo se n ko ise lati se ife iya re lo tun n dogbon lo sidii ise tiata lai je ki iya re mo rara.
Odun 1968 lo ko egbe osere ti ara re jo, mewaa pere si ni gbogbo won. Gbogbo awon to n baa sise lo si fun loruko inagije lokookan bii Arikuyeri, Oloye Ajere, Jacob, Papalolo, Aderupoko, Iya Ijebu, Adamson, Baba Eleko ati bee bee lo. Leyin opolopo odun ti won ti jo n sisde papo, Jacob, Papalolo ati Aderupoko pinnu lati lo da duro. O si se gbogbo atileyin to le se fun won lati da duro laaye ara won.
Ere olosoose re to pe ni “Omo Araye le ati Bata wahala” ti won se lori telifissan o soo di ilu-mo-on ka, ti oruko re si waa di ohun ti gbogbo eeyan mo.
Ko si eni to wa laye, ti ko lasiko idanwo tie. Lodun kan, Ajimajasan n bo lati ilu Eko, nigba ti moto mesidiisi V-Boot re lasidenti. Ijamba moto ohun po to bee, ti direfa re ku loju-ese nibe. Odun merin loun pelu si lo nileewosan.
 Leyin ijamba moto ohun lo si fun ara re ni inagije “Baba no regre”. Gege bo se wi “mo so ara mi loruko yii lati fi maa da ara mi lokan le pe, gbogbo nnkan n bo pada sipo, nigba tawon eeyan n fi mi seleya latari isele aburu to se si mi ni. Mo fi n so fun gbogbo eeyan pe, mi o kabamo igbe aye mi. Nitori, gbogbo ohun-ini mi lo tan sinu isele aburu naa. Ope ni fun Olorun. Ti emi ba si wa, ireti n be.
Ju gbogbo re lo, Ajimajasan ti ku. Ko si ju bi ose meji leyin ti Alagba Moses Olaiya Adejumo, eni ti gbogbo awon eeyan mo si Baba Sala ku, ti oun pelu ku yii.
e-max.it: your social media marketing partner