Tuesday 21 November 2017

Ewu to wa nibi abe dida fun omobinrin

Ewu to wa nibi abe dida fun omobinrin
YanjuAdegboyegaKii se ohun ajoji kaakiri agbaye pe, idaluu niseluu. Gbogbo eya kaakiri agbaye lo si ni asa ati ise won, eyi ti ko yo ile Africa ati Nigeria sile. Okan pataki lara asa iran Yoruba ati Nigeria lapapo ni ila kiko fun omo tuntun ti won ba bi. Ila kiko taa n so nipa re yi pin si ona meji. Fun omokunrin, awo felefele kan wa to maa n bo nnkan-omokunrin omo taa ba sese bi. Eyi ni awon oloola maa n ge kuro lati je ki nnkan-omokunrin omo naa jade. Ni ti obinrin, o je asa lati ge nnkan kan kuro ni oju-ara re. Idi ti won fi n se eyi, awon baba wa lo mo.
Laipe yii niwadii fi han pe, abe dida fun obinrin ko nii oore tabi anfaani kan to n se fun omobinrin yoowu taa ba daa fun. Koda, iwe mimo awon elesin mejeeji ko soro nipa ka dabe fun omobinrin. Lodun 2013, ijoba orileede Nigeria leyin ti ajo isokan agbaye ti fofin de abe dida fun omobinrin, eyi ti orileede yi pelu fowo si. Ijoba sewadii lawon ipinle marun-un kan lati mo bi oro abe dida fun obinrin se rese wale si nibe. Awon ipinle Ohun ni Ebonyin, Ekiti, Imo, Osun ati Oyo.
Abewo akoroyin wa sawon agbegbe ti ajo kan ti kii se tijoba ti n se idanilekoo fi han pe, awon eeyan ko ni eri kan lowo lori idi ti won fi n dabe fun omobinrin. Opo awon takoroyin wa si ba soro nibe lo ni ohun tawon ba lenu awon obi awon ni pe akoko, omobinrin ti won o ba dabe fun maa n se isekuse. Eekeji, pe kokoro kan ti oju kii ri, "Etare" maa ko si oju-ara omobinrin ti won o ba dabe fun. Eleeketa si ni pe, bi omobinrin ti won o ba dabe fun ba ti n dagba ni ki ni kekere kan to maa n wa loju-ara re yoo maa dagba ati pe to ba dasiko ati bimo, ti omo re ba fi ori kan ki ni ohun. Iru omo bee yoo ku ni.
Akoroyin wa gbo pe, lawon adugbo kan ni agbegbe Oke Ogun, eyi ti Kajola je okan nibe. Nise lawon obi maa n duro digba ti omobinrin won ti di olomoge, ki won to lo dabe fun won. Eyi to si maa n fa irora pupo fun iru omobinrin bee. Koda, o le sakoba fun ibegbepe re lawujo. Nitori, ti Oloola ti yoo dabe fun ko le see lai ti owo bo oju-ara re.
Nigba to n bakoroyin wa soro, alamojuto fun eto itaniji ohun labe ileese kan ti kii se tijoba, Action Health Incorporated, Arabinrin Adeniyi Zainab. O toka pe, awawi asan ni gbogbo ohun tawon eeyan n so naa, nipa abe dida fun omobinrin. Koda, o salaye pe aburu ti abe dida fun omobinrin n se po pupo ati pe ko soore kan to n se fun awon toro ba kan.
Adeniyi fi ohun ti won n ge danu loju-ara obinrin yii we ori nnkan-omokunrin pelu afikun pe bii ki won ge ori nnkan-omokunrin naa ni gige ti won n ge ti omobinrin. O salaye pe, awon obinrin naa ni eto si ki won gbadun ibalopo pelu okunrin, yato si ki won nibalopo nitori ati bimo nikan. O si wa toka pe, iwadii ti fi han pe ohun to le mu ki obinrin gbadun ibalopo ni won ti n ge danu lara obinrin lasiko ti won n dabe fun un naa.
Ko sai toka pe, okan-o-jokan ewu lo ro mo abe dida fun omobinrin. Lara ewu to si toka ni kiko kokoro HIV/AIDS nipase abe ti won ko se jinna, dida egbo si oju-ara obinrin. Eyi to je pe, ti won nko ba mojuto daadaa, o le fa ki awon kokoro arun aifojuri mi-in tun wole sii lara. Bee lo ni, opo igba ni eje kii da, eyi to si maa n mu emi omo mi-in lo. Nipari, o ni abe dida fun omobinrin le fa ki eni naa ma ri omo bi lasiko to ba fe se abiamo tabi ko je nipase ise-abe ni yoo bimo. O ni, eyi ri bee, nitori ti opo awon oloola lo maa n seesi di oju ibimo obinrin pa tabi ki won ti pa oju ile ito ati ti iyagbe papo.
Ninu oro oga agba oludanilekoo lori eto ilera nipinle Oyo, Abileko Bilikis Olawoyin. O toka pe, iwadii ti fidii re mule pe ko si anfaani kankan ti abe dida fun omobinrin n se fun ilera re. Bee si ni ko ni nnkan kan se pelu esin ati pe gbogbo agbaye lo ti fopin si asa ohun tipe. Ko si ye ki orileede Nigeria toun pelu fowo siwee adehun naa gbeyin rara.
Olawoyin pakiyesi akoroyin wa si awon asa kan to ti ka'se nile tan lasiko yi, nitori ti idi taa fi n see ko si mo. Akoko ni ila oju kiko, eyi taa n se latijo lasiko ti owo eru sise je ise gidi laarin awon eeyan wa. O salaye pe, nitori kawon obi tabi molebi le da eeyan won ti won ta l'eru mo ti won ba rii, ni won se n kola fun won. Sugbon, ti asa owo eru ko si mo. Eyi to si mu ila kiko pelu di nnkan tawon eeyan ko se mo. Eleekeji si ni kiko ojo, osu ati odun taa bimo si won nikun. Eyi to ni imo iwe kiko ati kika ti fopin si lasiko yi.
Okunrin oloola kan, Alfa Mojeed to bakoroyin wa soro soo di mimo pe, opo awon idanilekoo legbe awon ti se nipase ijoba ati pe awon pelu maa n so fun gbogbo omo egbe won lati ye da abe omobinrin mo. O si wa soo di mimo pe, ti oloola kan ba n dabe omobinrin lasiko yi, ayederu oloola ni ati pe kii se omo egbe won. Alfa Mojeedni opo awon oloola latijo ni ko nise mi-in ti won jokoo ti, ju ki won dabe lo. Sugbon, awon omo won lasiko yi nise mi-in lowo. Eyi to fi je pe, bi wonn ko dabe rara gan ati jeun won ko le nira.
Ni bayii ti iwadii fi han pe, ijoba ibile Kajola nipinle Oyo lo ni akosile abe dida fun omobinrin to po julo lorileede yii. Eyi ti won lo to ida mejidinlogorun-un. Akosile yi lo si mu ki won gbe eto itanji kan kale lawon ijoba ibile mefa mi-in nipinle Oyo, awon naa ni Kajola, Oyo WEest, Ogbomoso South, Ibarapa North, Akinyele ati Ibadan North.
Olawoyin soo di mimo pe, ile igbimo asofin orileede yii ti gbe ofin kan kale, eyi to fi ijiya ewon odun meji tabi owo itanran egberun lona ogorin naira lele fun enikeni ti owo ba te lori esun po dabe fun omobinrin. O lo si see se ki iru eni to ba se sofin ohun sanwo, ko si tun lo sewon.