Monday 29 April 2013

Iroyin a gbo sogba nu



Iroyin a gbo sogba nu!
Awon oluko LAUTECH fun ijoba Oyo, Osun ni gbedeke ose kan
 Awon omo egbe oluko (ASUU) ile eko ekose imo ero, LAUTECH ti fun awon ipinle mejeeji to jumo ni-in. Iyen ipinle Oyo ati Osun ni gbedeke ojo meje pere lati yan awon omo egbe igbimo alase fun ile eko naa.
Ta o ba gbagbe, lati igba tawon ijoba to wa lode bayii nipinle mejeeji to ni ile eko naa, ko tii si omo igbimo alase kankan to n moju too.
Se lasiko isejoba Otunba Adebayo Alao-Akala, okunrin gomina naa gbe awon igbese kan lati rii pe ile eko naa je ti ipinle Oyo nikan. Oro ohun lo si mu ki gomina ipinle Osun nigba naa, Omooba Olagunsoye Oyinlola gbe Alao-Akala lo sile ejo.
Ni kete tijoba si bo sowo egbe oselu ACN lawon ijoba ipinle mejeeji pinnu lati jo maa se inawo ori ile eko naa lo.
Laipe yii ni awon ijoba ipinle mejeeji yan gomina ipinle Eko tele, to tun je asiwaju egbe oselu ACN, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu gege bi olori igbimo alakooso (Pro Chancellor) fun ile eko naa.

Gbelegbo

Eyin ololufe wa. E ku amojuba GBELEGBO, ileese iroyin ori ayelujara Yoruba akoko iru re. Nibi te o ti maa gbo okan-o-jokan awon iroyin to n lo lawujo wa. Ire o.

Friday 19 April 2013

Iroyin a gbo sogba nu! Agbenuso egbe oselu Accord, Alaaji Lanre Latinwo ti soo di mimo pe laipe yii ko nii si egbe oselu kankan nipinle Oyo mo leyin Accord.
Latinwo nigba to n bakoroyin wa soro lori lile ti Gomina Ajimobi le awon omo egbe re ninu ijoba re ni " eru bi egbe Accord se n gberu si lojoojumo lo n baa.