Friday 23 February 2024

Oro Sunnukun

Ebi ati Ekun Ariwa Nigeria

Yanju Adegboyega

Ohun kan soso t’awon eeyan maa n so po maa n mu ki awon omo orile-ede yii sokan tele ri ni ere boolu alafesegba. Sugbon lasiko ta a wa yii, ohun kan soso to so gbogbo omo orile-ede yii papo ni ebi, o ga’ja f’owo meke.

Lasiko ta a wa ni kekere, aalo apagbe kan wa, ta a maa n pa laarin ara wa. Itan ijapa ari aja ni. Itan ohun lo si nii se pelu ai si ounje niluu ati ebi opapanla. Ninu aalo yii, a ri eko to nii se nipa iwa okanjua ati ohun to see se ko gbeyin re.

Itan ohun lo bayii, lasiko kan seyin, iyan mu pupo niluu awon eranko, eyi to si sokunfa owongogo ounje. Ni atako si asotele si ariran ti won ranse si lati ba won beere lowo Olorun fun ona abayo si isoro yii, nise ma ni ebi ati owon ounje yii maa tun n le sii. Owon ounje yii buru to bee ti won ti fi gbogbo ounje ti won ko pamo sinu aka tan patapata.

Nigba to d’ojo kan, gege bi olori fun gbogbo awon eranko, kiniun pe ipade gbogbo awon eranko jo, awon agba sa kuku ti soro pe, ebi kii wonu, ki oro miran o wo o, won si tun ni, ohun ta o je s’agba ohun ti a o jee. Pelu bi ebi se n lu won ni pasan, ni gbogbo awon eranko ra pala de ibi gbagede ipade.

Nigba to si bere oro re, kiniun, eni tie bi foju han lara tie pelu ha fun re “kehe kehe”, o ni ko si ani-ani pe iyan to mu yii n ba onikaluku finra pupo, eyi to si ti sokunfa iku opo awon eranko akegbe won. O toka pe, a fi ki won o gbe igbese kiakia, afaimo ki nnkan o ma buru ju bayii lo.

Bayii ni won pinnu igbese ti won yoo gbe e. Ohun ti won fenu ko si nip e, ki onikaluku maa fa iya won kale, ki won si maa pa won je, ki gbogbo iran eranko ma ba a parun kuro lori ile aye. Won gba pe, ki onikaluku maa mu iya re wa sibi gbagede ipade leyo kookan ki gbogbo won si dijo maa je e, ki iran eranko si le wa laye sii.

Gbigbo ti aja gbo oro yii, eyi ti ko ba fi tele adehun ti gbogbo awon eranko fenu ko le lori yii, iwa imotara-eni nikan aja lo mu ko fi oru oganjo boju mu iya re kuro nile, to si se bee mu un kuro laarin ilu. Se aja nifee iya re pupo, to bee to fi ni, o ya oun lara lati ku, ju ki oun fa a kale fun awon eranko to ku lati pa a je, ki iran eranko le si maa waye lo. Bayii ni aja sa kuro niluu lo sibi kan to fara sin leyin to ti gbe iya re pamo si orun.

Gbogbo awon eranko, to fi mo ijapa, ologbon ewe lo tele adehun ti gbogbo awon eranko jo se. Won n mu iya won was i gbagede ipade, won si jo n je won. Sugbon, lojoojumo, aja maa n lo sibi kan nibi to ti maa n fi orin pe iya re. Orin naa lo bayii:

“Iya, Iya ta’kun wa le o.

Alujanjan kijan.

Gbogbo aye lo pa yeye e je.

Alujanjan kijan.

Emi aja gbe tire, o d’orun.

Alujanjan kijan….

Leyin ti aja ba ti korin bayii tan, iya re yoo ju okun kan sile fun un, eyi ti aja yoo si fi gun oke lo sorun, nibi ti yoo ti je ounje a je yo ati a je ran ikun. Nigba to ya, awon eranko t ku bere sii fura si aja, nitori nise lo n dan, tie eke re si n yo jade. Nigba to di ojo kan, ijapa, ologbon ewe so aja, o si mo asiri re.

Lojo keji, ijapa yo lo sibi ti aja ti maa n pe iya re yii, o yi ohun re pada, o si korin bi aja se maa n ko o. Iya si ju okun sile fun un looto. Bi ijapa se n gun okun yii lo n aja yo, inu re si ru pupo. Lo ba bere sii sunkun, to si n fi ohun-aro korin pe, ohun orin onijibiti ni iya oun f’eti si ati pe se iya oun wa mo ohun oun mo ni? Inu bi iya aja, lo ba fibinu geo kun laarin meji. Bayii ni ijapa ja lule lati oke, ti igba eyin re si fo petepete. Agbara kaka si ni ijapa fi rin de odo ikamudu to ba a to igba eyin re po pada.

Yato si pe, itan yii ko ni logbon, awon Yoruba lo iriri won nipa owon ounje lati salaye idi ti igba eyin ijapa se ri bo se ri lonii.

Sugbon, se ka ma f’eko tan ina funra wa, ebi wa niluu lasiko yii. Te e ba ri fonran fidio kan lori ikanni ayelujara ni nnkan ose meji seyin, e o jerii sii pe looto ni owon ounje n ba orile-ede Nigeria finra. Ninu fonran yii, awon eeyan kan n ja lati gba buredi ogorun-un kan naira laduugbo Isale Eko, bee si ni won n lu ara won nitori ati ri gba nibe. Yato sawon okan-o-jokan isoro ti orile-ede yii n koju, owon gogo awon ohun tie nu n je to n ba Nigeria finra buru to bee, to ti n dunkooko mo emi ati igbaye wa.

Looto, isoro ounje kii kuku se ohun tuntun l’aye. Orile-ede kookan lo n mo ilana ati ogbon to n da soro ebi lodo won. Ta a ba lo sinu iwe iranti, niwon odun 1950 si 1960, orile-ede India nisoro owon ohun t’enu n je. Isele yii le to bee, ti won fi fun ile naa ni inagije orile-ede “abo alagbe”. (Begging bowl nation).

Irufe isele yii ti n sele lat’igba toju ti wa lorunkun, sugbon orile-ede kookan ni yoo wa woroko fi s’ada lori re. Ta a ba lo sinu itan Bibeli, nigba ti iyan nla mu ni orile-ede Farao, iyen Egypt. Farao ra opo ounje lati awon ilu mi-in, won si ko won pamo sinu aka. Koda, won tun se agbega fun Josefu sipo olootu ijoba lati maa samojuto asiko owon ounje naa.

Isele owon gogo awon ohun t’enu n je, to n lo lowo lorile-ede yii lasiko ta a wa yii ti fe pin emi awon eeyan. Ounje atawon ohun mi-in lo ti won koja ibi t’eeyan l’ero ri. Ehonu n fojoojumo waye kaakiri. Bi owo oja atawon ohun t’enu n je se n fojoojumo gb’owo lori n ko’ni lominu. Bi oja se n deru ba owo, ti feree le to bee, ti opo awon molebi ko le da enu won bo mo. Apo simenti ikole ti le ni egberun kan, nigba ti apo iresi ti feree to egbrun lona ogorun-un naira. Lasiko ta a wa yii, owon gogo ounje ti n ti awon omo Nigeria jade sawon oju opopona lati fehonu han l’awon ipinle bii Niger, Kano, Osun ati Eko. Eru si ti bere sii baa won eeyan to mo nnkan ti isele yii le bi.

Ajo to n seto ounje lagbaye, World Food Programme, WFP, ninu iwe re to gbe jade laipe yii ni eru ti n ba pe, wahala ohun le nipa buburu lori awon okoo le lugba omo orile-ede yii, gege bi orile-ede eniyan dudu to ni eeyan to po julo nile Africa ati eekefa l’agbaye. Ko to dasiko yii, ominu ti n ko ajo WFP lori, awon omo orile-ede yi to to milionu merinlelogorin, eyi tii se ida metadinlogoji gbogbo awon omo orile-ede yii. Won toka si awon isele bii rogbodiyan ati eto aabo ti ko dara, bi nnkan se n fojoojumo won ati ipa ti ayipada oju ojo le ni lori ohun t’enu n je. Ajo WFP se afojusun pe, awon omo orile-ede yii ti won to milionu merindinlogbon aabo ni yoo foju wina ebi opapanla nigba ti yoo ba fi di osi kefa si ikejo odun yii lasiko ire-oko yoo ti maa dinku.Wahala to si n sele ni ila oorun ariwa orile-ede yii, eyi to ti so awon eeyan ti ko din ni milionu meji le meji di alai nile lori pelu bo se se akoba fun awon milionu merin le merin mi-in lati ri ounje je l’awon ipinle bii Borno, Adamawa and Yobe kun isoro to wa nile ohun.

E je ka wa pada sibi ipade awon eranko, gbogbo wa pejo lati wa egbo dekun fun alujannu to n je ebi yii. Sugbon, kin i esi t’awon olori wa ni Nigeria fo soro ohun? Ninu oro tie, Aare Tinub u pase ki ile-ise ijoba apapo to wa fun ise ogbin lati ko awon ire oko bii agbado, jero ati gari to to egberun mejilelogoji toonu jade. O tun se ipade po pelu awon gomina nile ijoba Aso Rock lojo alamisi ose to lo, nibi to ti so fun won yanya pe, kiko ounje wole lati ile okeere ko ni ona abayo si isoro to wa nile naa. Tinubu tun rawo ebe sawon gomina lati karamaasiki inawo si eka ipese eso, eran osin ati eto kiko ounje pamo nidii ise ogbin, ki ounje le po yanturu.

Sugbon, nigba ti won yoo maa fesi soro owon gogo ounje, nise l’awon gomina apa ariwa huwa bi omugo, ti won kopa irufe eyi ti aja ko lasiko iyan. Eyi ti won n fogbon ati iwa imotara-eni se nipa siso oro owon ounje ohun di ti eleyameya. Latile wa lo ti je pe, kii si ani-ani pe, iwa imotara-eni nikan l’awon asiwaju oke oya maa n hu, bi igba to je pe kadara won ni lati maa da se ti won nikan, ni atako si ajosepo gbogbo eeyan. Eyi lo mu un wa siranti, oro kan t’awon Yoruba maa n so pe, eni ti yoo sun l’ebi ni, koda ti won bag be abo iyan kan si ori pepe fun un, eku yoo debe lati ja abo ohun bo.

Aja, onimo-tara-eni akoko ni gomina ipinle Niger, Mohammed Umar Bago. Ki ni ifehonu han waye ni Minna ni nnkan bi ose meloo seyin, nise Bago f’ofin de tita awon ohun t’enu n je lopo yanturu fun awon onisowo ounje lati guusu orile-ede yii l’awon oja won. Gege bi aja kan naa, Emir Kano, Alaaji Aminu Bayero naa gbe iya re lo s’orun. Nigba to n gba iyawo aare, Oluremi Tinubu lalejo l’aafin re ni bi ose meji sasiko yii. Bayero ro obinrin akoko lorile-ede yii lati jise fun oko re, Bola Tinubu pe, ebi, iyan ati eto aabo ti ko fara to n daamu orile-ede yii ti di oro ai l’aso lorun paaka, eyi to ye ko ti to apero fun gbogbo omo eriwo.

Nigba to tun soro, nipase ogbufo, leyin opolopo alaye to ti waye lori bi awon eeyan ariwa se n ri olu ilu orile-ede yii gege bi ti won nikan ati anfaani ti igbese ijoba apapo n gbe pelu bi won se n bu enu-ate lu igbese ijoba apapo lati ko awon oofiisi kan ni ile-ise oko ofurufu ati banki agba orile-ede yii lo siluu Eko, Bayero tun m’enu ba oro yii.

Nibi ipade awon omo igbimo alase awon oba alaye ile Hausa to waye lojo wesidee ose to koja lo lohun-un nile Arewa niluu Kaduna, Sultan ilu Sokoto, Muhammad Sa’ad Abubakar atawon oba alaye re naa huwa aja, alujanjan kijan, nigba ti won gbe iya won lo s’orun. Won kilo pe, o see se k’awon eeyan ariwa fehonu nla han ti ise, ebi ati eto aabo to mehe yii ba n te siwaju, ti ijoba o si ri nnkan se si i.

Ko si iro nibe pe, owon gogo ounje to wa nita yii n ta awon eeyan lori. Won tun soro lori bi gbogbo awon isejoba to ti n koja ni Nigeria ko se ni iwa olori rere, eni to ni afojusun ojo ola.

Sugbon, ta a ba fe so ooto oro, o ti pet i ikilo ti n wa pe, orile-ede Nigeria yoo koju isoro own gogo ounje. Ko sese bere lonii, ko sis i okan kan ninu awon olori yii to f’eti si ikilo yii nigba naa. Abi, nigba t’awon Fulani daran daran to n da eran daran n se ikolu s’awon ipinle ta a mo gege bi ibi ti ounje ti n wa bii Benue, Plateau, Adamawa, Taraba, Kaduna, Yobe, Niger ati Jigawa, nibi ti won ti n pese iresi, ata, ege, isu, ogede dodo, ope oyinbo, agbado, ewa, ati epo pupa.

E dakun, ki ni isejoba Muhammadu Buhari se nigba naa? Ogbon won i won da si ifehonu han alagbara awon ekun to ku l’orile-ede yii lasiko naa? E je ka gba pe, isoro ohun fon ina soju ni kete tijoba Tinubu kede iyokuro owo iranwo ori epo lojo to n gba isakooso l’osu karun-un odun to koja ati isodokan iye ti won n se pasipaaro owo ile okeere. Nitori naa, a le se bi pa o mo pe, asiko isejoba Buhari ni isoro oro owon ounje oni bere, nigba t’awon agbe ko le lo sinu oko won mo, nitori iberu bojo ai si eto aabo fun won.

Iwadii ti je ka mo lati awon ipinle to si l’oore-ofe lati maa pese ounje, pelu bi eto aabo se n se segesege pe won ti f’enu ko pe, won o nii je ki awon ounje ohun was i apa guusu mo. Ohun ti mo wa n ro mi pe, ki lo le sele, t’awon ipinle to wa ni guusu naa ba ni k’awom ohun-elo to se pataki lati odo won o ma jade lo si ariwa mo. Ki ni yoo je ipa ti yoo ni? Bi apeere, ki won ma jee ki epo petiroolu de apa ariwa?

Lasiko ti gbogbo omo orile-ede Nigeria foju wina owon gogo ounje, awon asiwaju apa ariwa n fi iwa imotara-eni nikan pariwo pe nnkan o rogbo fun won. E dakun, lasiko ti omo won, Buhari n mu aye nira fun gbogbo awa omo orile-ede yii, eemeloo ni Emir Kano ati Sultan Sokoto pariwo sita? Irufe ogbon alumokoroyi lati je ko dabi igba to je guusu lo n f’ebi p’awon omo Nigeria yii, ti awon eya ariwa fe lo yii ko feree yato si ona lati gbe ebi gbogbo oro isoro Nigeria yii kuro lori ara won.

To ba je p’awon baba nla won ni ariwa ti mojuto iwa “a bimo, ma to o” ti gbogbo eeyan mo si “Alumajiri” lonii, o see se ka ma nisoro awon onisunmomi to n ba fa finra, eyi ti orile-ede Nigeria tin a opolopo tirilionu owo naira le lori, to si ti gba emi opolopo. Eyi to tun fara jo o, nit i okunrin omo bibi ipinle Borno nni, Mohammed Yusuf, eni to je oludasile egbe awon alakatakiti esin Musulumi, Boko Haram. To ba je p’awon onimotara-eni asiwaju ariwa ko faaye gba egbe yii lati gbeeru ni, o see se ki orile-ede Nigeria o ma maa foju wina ai si eto aabo to peye, eyi to sokunfa owon gogo ounje lasiko yii.

Ona abayo kuro ninu isoro owon gogo ounje to n ba wa finra lorile-ede yii kii se k’awon kan o fee so ebi oro di ti igun kan. Koda, ki Tinubu kede ilu o fara ro nidii eto ogbin ko le tan an, nise lo ye ko sun, ko takaaka, gege bi olori ilu lasiko ti nnkan o rogbo yii. Bo se se pataki lati wa ojutuu soro owon gogo ounje yii, ko to maa mu emi lo, lo ye ki ijoba wa ona ti yoo je onigba pipe ati eyi ti ko nii maa gbon owo lo lati wa ona abayo. Ona akoko, ni ka doju koi se ogbin pelu gbogbo okun ati agbara wa.

Asiko yii lo ye ki Tinubu lo wa iru okunrin ojogbonm onimo nipa eto ogbin nni, Adedunmola Hezekiah Oluwasanmi, eni ti gbogbo eeyan n kan saara si lori ilana to lo lori eto ogbin ile-eko giga yunifasiti Obafemi Awolowo lojosi. Okunrin Oluwasanmi yii si gbodo l’awon eeyan to tip o ito omo re nipa eto ogbin si lenu kaakiri orile-ede Nigeria. Nise lo ye ki ijoba se koriya gidi fun awon agbe, ki won si rii daju pee to aabo won fokan bale, eyi ti yoo jee ki won le pinnu tabi gba lati pada s’oko. Eyi ti yoo mu ki ounje o sun wa bo, ti yoo si se bee mu adinku ba owo gegegee ti won fi n le ounje. O ye ki ijoba seto, ki awon eeyan to ba n dokoowo nidii ise ogbin le maa ri ere gidi je, ti ere ajepajude ti yoo tun mu nnkan le fun mekunnu ko si nii si.

Bi apeere, ki lo de ti ijoba ko se koriya fun awon gomina ile Yoruba, ki won pada sidii ogbin koko, eyi to n se daadaa l’oja agbaye lasiko yii, ki won se koriya fun epo pupa ni ila oorun guusu ati awon ohun ogbin to n se daadaa ni ariwa?

Ko si ani-ani pe, lonii, orile-ede India ti gbogbo agbaye fi n seleya nitori iyan ati ebi to foju wina niwon odun 1960 gbe igbese akin, eyi to pada di aseyori ounje a ni to ati a ni seku fun won. Lonii, okan pataki ninu awon orile-ede to n f’ounje ranse s’awon ilu ile okeere fun titan i India.

Olori to ba looto, to si nipinnu le se iru aseyori orile-ede India ni Nigeria naa. Eyi ti gbogbo awon ekun to wa ni Nigeria yoo se maa gbe iya won salo fun ipalara bi aja inu itan ta a so saaju, irufe bi awon eeyan ariwa se n se lasiko yii, nise lo ye ka jo wa ojutuu soro to wa nile yii. Ka si jo fopin si isoro owon gogo ounje to n koju wa. Awon Yoruba ni, afaa to n’iyan o mu ni, omo re o nii je tira o.

Oro Sunnukun re o, e je ka jo foju sunnnukun wo o!

Wednesday 14 December 2022

Olorun lo pe mi, mi o nii l’okan lati j’oba – Oba Segun Joseph Adetuwo

Olorun lo pe mi, mi o nii l’okan lati j’oba – Oba Segun Joseph Adetuwo

Ta a ba n soro awon ilu nile Yoruba, okan pataki niluu Igodan Lisa lain awon ilu ile Ikale nipinle Ondo. Opo awon nnkan niluu yii fi yato sawon ilu to ku kaakiri ile Yoruba ati kaakiri agbaye. Laipe yii ni akoroyin wa, YANJU ADEGBOYEGA se iforowero pelu Oba ilu Igodan Lisa, Oba Segun Joseph Adetuwo lori foonu. Okan-o-jokan oro ni won si jo so, e maa ba wa kalo.

Alariya Oodua – Kabiyesi, e so fun wa ni soki nipa ilu Igodan Lisa?

Kabiyesi – Okan lara awon ile Yoruba ti won n pe ni Ikale mesan-an niluu Igodan Lisa. Baba mi, Iku Ijamofo lo te ilu yii lopo odun seyin. Iyawo marundinlogota ni baba mi yii fe.

Opolopo omo ni baba mi yii bi, won si po to bee, ti won fi te odidi ilu. Awon kan lara awon omo yii lo sile ibomi-in, awon to je obinrin lo sile oko, nigba tawon to ku duro sile. Nitori naa, ta a ba wo gbogbo awon omo yii to je okunrin, a ni to idile merinlelogbon to letoo si gbogbo nnkan ta a ba n se ninu ilu yii. Ohun to si mu ki ilu Igodan Lisa yato si gbogbo awon ilu to ku nile Yoruba ni pa o le fe ara wa l’oko tabi iyawo titi dasiko yii. Gbogbo awon omo Iku Ijamofo ko le fera won, yato sawon to telee wa lati wa jokoo ti i nigba to wa te ilu Igodan Lisa. Bi awon eya Urhobo.

Idile temi ti jade ni akobi Iku Ijamofo, Lemikan l’oruko re n je. Looto, o ku saaju baba re. Sugbon, o lowo pupo nigba aye re. Itan so pe, nigba ti baba re, Iku Ijamofo rii pe eeyan nla ni Lemikan, omo re yii, loju aye re lo ti fun un ni gbogbo nnkan to to si i ninu ogun re, ko to ku.

Lemikan naa gbiyanju, iyawo mokanlelogbon lo ni. O si bi opolopo omo.

Alariya Oodua – E seun, Kabiyesi. Bawo abi ilana won ni won fi n j’oba niluu Igodan Lisa?

Kabiyesi – Emi ni oba eleekeji ti won maa je niluu Igodan Lisa. Eni to je oba akoko ni Oba Paul Abiodun Akinsola.

Odun metadinlogun ni won lo nipo. Leyin ti won si ku, ti won se oku won tan ninu osu kin-in-ni odun 2021. Won kede pe, ipo yen sofo.

Ohun kan to jo emi loju ni pe, saaji asiko yen, lati nnkan bi odun merin ni won ti maa n so fun mi pe oba ni mi. Odun 2016 ni mo pada de lati ile America at’igba yen ni Olorun ti fi han awon kan pe won ri ade lori mi. Ti mo ba lo si soosi kan lati lo josin, ti elemi ba wa nibe, yoo pe mi jade..

Lojo kan ninu osu kin-in-ni odun to koja, mo wa laduugbo Amuloko niluu Ibadan. Baba mi ninu Oluwa kan lo n se akanse adura olojo jimoh meje. Boya jimoh kerin tabi ikarun-un ni mo tie lo, mi o le ranti mo. O bo sasiko ti won n se isinku oba wa yen lowo. Bi won se n seto yen lo, alufaa pase ki gbogbo awon to wa lowo eyin jade bo siwaju. Ti mo ba lo sawon eto bayen, owo eyin ni mo maa n jokoo si, ki n le raaye sadura daadaa. Bi mo se n jade bo siwaju, wolii yen ni “Mo ri ade ide lori arakunrin yii, irukere ati ileke pelu.”

O ni, se idile oba ni mo ti wa ni? Sugbon, nitori ti mi o kii fe gbo ise yen. Ki n to dahun, mo go won ninu mi pe rara. Loju ese ni wolii yen so pe, “arakunrin yii si n go mi ninu emi.” O ni ki n ri oun leyin eto.

Nigba ti mo yoju si i leyin eto, o so orisirisi oro. O salaye pe, ade ti oun ri lori mi lati orun ni. O beere pe, se enikeni ko so fun mi ri, mo si ni won ti maa n so fun mi. O ni, o di dandan ki de ade yen loju aye. Ki ayanmo ati akosile yen le wa simuse

O beere ohun ti won n se lowo niluu wa ba a se n soro yii. Mo ni won n se isinku Kabiyesi to gbe’se. O ni oun pelu ti ri i. O wa gba mi nimoran lati pada siluu leyin ose kan ti won ba pari isinku yen, ki n si lo so fun eni to n dari ilu lasiko yii pe Olorun lo ran mi wa lati wa tun ilu Igodan Lisa se.

Nitori naa, leyin ose kan, mo lo ri Baba Lisa to n sakooso ilu. Mo si so fun un. O l’oun ti gbo, ka maa lo, ka pada wa lojo keji. Boya o fe lo beere si i ni o, emi o mo. Nigba to d’ojo keji, a pada lo ba a. O si ni oun ti gbo, sugbon ile kan ti baba mi n ko lowo, ti ko pari lati odun yii, ki n lo pari re na. O ni ise po fun mi lati se, bee si lawon atunse kan wa ti maa se. Ko si pe, ti won fi kede pe ipo yen ti sofo.

Bayii ni mo fi erongba mi han. Awon mefa mi-in naa so po wu awon, a si je meje.

Sugbon, nigba ta a nipenija oro aabo niluu. Won ni ki gbogbo wa mu egberun lona igba naira wa lati ran ilu lowo. Enikan ko san owo yen, o l’oun o lowo. Bayii la ku mefa. Meji lara wa lo je omo oba to gbe’se. Won ni baba won ti so, ko to ku pe t’oun ba ku tan, awon ni ko gba ipo yen. Pelu pe won mo pe idile merinlelogbon ni wa.

Yato sawon meji yii, awon meta to je agbaoye niluu naa lawon letoo sipo yen. Mesan-an lawon agbaoye to wa niluu, awon si ni afobaje. Opo awon awuyewuye lo tie waye lori oro yen. Sugbon, mo je ko ye won pe Olorun lo pe mi lati wa j’oba.

Nnkan mi-in ti won tun so ni pe, mo si ni obi laye. Nitori ti, baba ati mama si wa. Awon kan ni eni tawon obi re ba si wa laye ko le j’oba. Ninu molebi temi, awa meji la jade lati dupo yii. Nibe lawon molebi kan tun ti n so pe, enikan gbodo ju’wo sile fun enikan ni ati pe omode lo gbodoju’wo sile fun agbalagba. Nitori naa, emi ni ki n fipo yen sile fun enikeji, nitori to ju mi lo.

Mo si kuku ti so fun won tele pe, mi o setan lati dupo pelu enikeni, sugbon Olorun lo ran mi lati wa j’oba niluu yii. Nitori naa, tawon ilu ba fe mi, ti won nigbagbo ninu oro Olorun. Deedee ni.

E ma gbagbe pe, idile temi ni akobi ninu omo Iku Ijamofo. Nitori naa, a gbodo rii daju p’awa la j’oba yii. Ka si wa maa yii po laarin ara wa. Bi bee ko, ta a ba ti lo so anfaani yii nu, a le ma rii mo ni ogorun-un odun to n bo.

Bayii ni ilu gbe igbimo oluyewo kale. Awon igbimo yen ninu ipade won kan tie ni otosi kii j’oba, won l’eni to ba fe j’oba gbodo le gbe eru ilu. Nitori naa, won ni ki gbogbo wa lo san milionu meji enikookan ati p’owo yen ko see gba pada. Awa kan faramo on, awon kan o faramo on. Ohun to tun wa le nibe ni pa a ti gbodo sanwo yen ko to d’ojo ti won maa se ayewo fun wa..

Wolii kan si ti jise fun mi ri pe, isegun kan to wa fun mi ni pe, gbogbo nnkan tiluu ba ni ka se. Ki n rii daju p’emi l’eni akoko ti yoo maa se e. Lojo iforowero yen, wakati kan ataabo ni mo lo niwaju won. Opolopo ibeere ni won beere lowo mi. Ohun kan ti mo se ni pe, mo farabale dahun awon ibeere won. Mi o si dide kuro niwaju won titi mo fi pari.

Leyin ayewo ati iforowero yen, mo pada siluu Eko. Sugbon mo rii daju pe mo n wa larowoto nigba yoowu ti won ba nilo mi. Nigba ti esi jade, awa meji la yege julo. Ti kii ba sii se pe Olorun n fe mi nipo yii ni, a o le so ohun ti ko ba sele. Laarin awa mefeefa, emi ni mo feree nigbagbo ninu Olorun julo, ti mo si ni majemu pelu re. Koda, enikeji mi beere lati gba owo re pada lowo awon igbimo yen. O nipo oba ko ye ko je tita. Nigba ti won beere boya emi naa fe gb’owo mi pada, mo ni mo ti fun ilu. Ki won lo lo o fun idagbasoke ilu.

Nigba ti mo so pe, mo ti fun ilu l’owo, awon eeyan patewo fun mi. Leyin naa ni won mu ojo fun idibo. Sugbon, ko to d’ojo yen, opo awon igbese aburu ni won n gbe. Eni to wa lati molebi mi yen gan tie lo fi ara re j’oba, ko to di p’awon ilu le e danu. Nitori, emi ni gbogbo ilu n fe nipo.

Alariya Oodua – Kabiyesi! Ki l’awon nnkan tee ti le se lara awon ileri te e se?

Kabiyesi – Ohun kan ti mo koko se, bi mo se depo ni lati maa lo ki gbogbo awon ijo Olorun to wa niluu lojo sannde kookan, ki n si mo ki nipenija ti won ni. Leyin eyi, awon osise ile iwosan alaboode to wa niluu wa ki mi. Won ni ko si geeti lenu ona won, mo si seleri lati se e fun won. Maa gbe e fun won lose to n bo lagbara Olorun, nitori ti won ti n sise lori re lo. Yato seyii, awon osise ile-eko girama wa nibi wa ki mi lanaa. Won salaye pe, awon orule won n jo. Nitori naa, mo beere awon igbimo ile-eko won, nitori ti mi o fe maa se nnkan kan lai je k’awon eeyan mi maa mo sii. Mo ni ki won fun mi ni bi maa se r’awon igbimo yen ba soro lati mo nnkan ta a ba le se fun won. Nitori naa, a ni ero fun awon naa.

Ohun mi-in ti mo tun n se ni pe, mo sagbekale igbimo eleto-aabo. Nitori ta a nipenija eto aabo pupo. Nitori naa, mo gba awon osise eleto-aabo mejo lowo ara mi. Laarin emi ati olori odo ilu, mo so fun un pe maa sanwo awon osise eleto-aabo yen l’apo mi fun osu meta akoko. Lori eleyii, ko siranlowo kankan lati ibi kan kan lasiko yii. Laarin emi ati Olorun nikan ni, a fi ta a ba r’eni to fife han si nnkan to wa nile yii. Mo si le gbe e fun osu meta na.

Leyin eyi, a n sise lori okan-o-jokan awon igbimo fun ise idagbasoke ilu.

Alariya Oodua – Gege bi kristeni, ki lajosepo to wa laarin eyin atawon elesin to ku, paapaa awon musulumi ati elesin ibile?

Kabiyesi – E seun. Gege bi oba niluu, looto awon eeyan maa n so pe oba o kii l’esin. Iro ni! Oba l’esin, sugbon gbogbo esin ni ti oba. E je ki n bere bayii. Mo n b’awon elesin ibile soro lojo wo pe, mi o wa lati pa esin won run. Sugbon, ki won fun mi laaye lati jise ti Olorun ran mi. Ki won je ki alaafia j’oba niluu.

Won mo pe, mi o kii je obi, mi o kii mu oti, mi o de kii j’eran. Mo so fun lati ibere pepe pe, mi o kii se gbogbo nnkan wonyi. Ko ma wa je pe, nigba to depo tan lo to so fun wa p’oun o kii se nnkan kan. Mi o kii j’eran ewure, koda o loju iru adie ti mo maa n je.

Sugbon, mi o nii tori pe, mi o kii se nnkan wonyi. Ta a ba r’eni to se, to si je nnkan yii ni ohun itanran re. Ki won gba, ki won fun awon to maa n je e. Mi o wa sibi lati pa asa ati ise ti won ti n se run. Kii se nnkan ta a ran mi wa se niyen.

Iru odun “Ere” bayii, maa darapo mo won lati se e. Odun “Ijesu”, maa darapo mo won lati se e. Nigba ti akoko re ba to.

Ni t’awon musulumi, won wa ki mi nibi ni bi ojo meta seyin. Won si sadura. Emi naa gba won towo-tese, mo si sadura pe won yoo mo asiko ti oba je yii si rere. Mo so fun won pe, mo l’awon musulumu l’oree to po niluu Eko ti mo ti wa. Okan tie wa, to je Alaaji. T’awon eeyan ba ri okan ninu wa, ibeere ti won o koko beere to ba je emi ni won ri ni “Pasito, Alaaji n ko? To ba si je oun naa ni won koko ri, won a ni “Alaaji, Pasito n ko? Nitori idi eyi, a sun mora wa gan ni. Esin tie kii se temi, esin temi naa kii se tie. Mo so fun won pe, mo l’awon ore musulumi to po, ta a jo n se daadaa.

Mo gba won niyanju lati lo wa ile, ti won yoo fi ko mosalasi. Nitori, wiwa mi yii, nigba ti yoo ba fi to odun marun-un sasiko yii, eni to ba maa ra ile niluu yii yoo mura o. Ohun ti Oloun fi han mi niyen pe, ile kiko ti yoo sele laarin asiko yii s’odun to n bo yoo lagbara pupo.

Logan ti mo si d’ori apere yii, awon molebi bii merin to wa loke okun lo ti ni, ni bayii ti oba ti je yii, awon fe wa sile lati wa ko’le. Awon meji ninu won ti ra ile pulooti meji-meji, a si n b’awon to ku wa tiwon lowo.

Awon molebi kan wa, ti won ti kuro niluu yii lati nnkan bi ogorun-un odun. Lasiko ta a n mura igbade mi, won ni ti Olorun ba gbe mi depo, awon n pada bo siluu yii. Ko din ni eni meedogun to wa ninu molebi yii. E si mo pe, bi idagbasoke ba se n po si niluu, ni iye ti won n ta ile yoo maa goke sii.  Nitori naa, awon musulumi ti mo ni ki won lo wa ile yen, nigba to ba to akoko, maa mo nnkan ti maa se lati ran won lowo.   

Alariya Oodua – E seun, Kabiyesi. Ki le le so nipa Ambassador Ibironke Oluwayemisi Onitiju?

Kabiyesi – Okan lara awon arabinrin wa ni. Oun ni Yeye Jima ilu Igodan Lisa. Omo wa ta a le fi yangan ni. Omo wa, to rin irin-ajo, sugbon ti ko gbagbe ile ni. Omo wa, to l’aanu si gbogbo eeyan ni.

Ona ti mo gba mo on ati awon iroyin ti mo gbo nipa re fi han pe kii se po n seranwo f’awon omo ilu yii nikan. T’eeyan ba ti so ede Ikale, o ti gbagbo p’eeyan oun ni.

Adura mi fun un ni pe, aabo Olorun yoo maa wa lori re. Ki Olorun ma fi sile. Ise ti Olorun fi ran an, ki Olorun fun un ni oore-ofe lati le je e nirorun. Ki ile ati ona re o ma baje.

Mo so fun un pe, ni bayii ta a mora. O o ri awon nnkan ti Olorun yoo maa se laye re. Mo sadura fun un pe, gbogbo nnkan rere to beere fun ati eyi ti ko beere fun ni Olorun yoo se fun un. Nitori to nifee ilu re pupo.

A sun mora pupo. Gbogbo igba la maa n soro, a o si le se ose kan, ka ma soro.

Alariya Oodua – Gbogbo wa la mo pe, t’eni meji ba n ja si nnkan, enikan ni yoo ja mo lowo. Ni bayii, to je eyin lo ja mo lowo. Ki l’awon igbese te e ti n gbe lati fa oju awon te e jo dupo mora?

Kabiyesi – A o tii gbe igbese kankan to po lori eyi, sugbon, omo wa kan wa to n gbe niluu Ibadan, Dokita Oyedele, mo so fun un pe, yoo wu mi ko je alaga igbimo ti yoo petu s’aawo laarin awa ta a jo dupo. Mo so fun un pe, ko wa awon eeyan merin mi-in ti won le jo sise po ninu igbimo yen.

Nitori, nise lo ye ka jo sise papo lati mu ilosiwaju ba ilu wa. Nitori naa, lori oro ipetu s’aawo yen, a si wa lori re. Mo si mo pe, pelu asiko ati adura, a o bori gbogbo isoro yii.

Alariya Oodua – E seun, Kabiyesi. A nigbagbo pe, ta a ba tun kan sii yin, e o gba wa laaye?

Kabiyesi – Eyin le seun pupo ju. Gbogbo igba te e ba se tan, la o maa gba yin laaye.         

         Akiyesi!

O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA monde ojo kejila osu kejila odun 2022

Wednesday 30 November 2022

Olorun lo pe mi, mi o nii l’okan lati j’oba – Oba Segun Joseph Adetuwo

Olorun lo pe mi, mi o nii l’okan lati j’oba – Oba Segun Joseph Adetuwo

Ta a ba n soro awon ilu nile Yoruba, okan pataki niluu Igodan Lisa lain awon ilu ile Ikale nipinle Ondo. Opo awon nnkan niluu yii fi yato sawon ilu to ku kaakiri ile Yoruba ati kaakiri agbaye. Laipe yii ni akoroyin wa, YANJU ADEGBOYEGA se iforowero pelu Oba ilu Igodan Lisa, Oba Segun Joseph Adetuwo lori foonu. Okan-o-jokan oro ni won si jo so, e maa ba wa kalo.

Alariya Oodua – Kabiyesi, e so fun wa ni soki nipa ilu Igodan Lisa?

Kabiyesi – Okan lara awon ile Yoruba ti won n pe ni Ikale mesan-an niluu Igodan Lisa. Baba mi, Iku Ijamofo lo te ilu yii lopo odun seyin. Iyawo marundinlogota ni baba mi yii fe, okan lara awon iyawo re si n je Iya Ewe Faro.

Opolopo omo ni baba mi yii bi, won si po to bee, ti won fi te odidi ilu. Awon kan lara awon omo yii lo sile ibomi-in, awon to je obinrin lo sile oko, nigba tawon to ku duro sile. Nitori naa, ta a ba wo gbogbo awon omo yii to je okunrin, a ni to idile merinlelogbon to letoo si gbogbo nnkan ta a ba n se ninu ilu yii. Ohun to si mu ki ilu Igodan Lisa yato si gbogbo awon ilu to ku nile Yoruba ni pa o le fe ara wa l’oko tabi iyawo titi dasiko yii. Gbogbo awon omo Iku Ijamofo ko le fera won, yato sawon to telee wa lati wa jokoo ti i nigba to wa te ilu Igodan Lisa. Bi awon eya Urhobo.

Idile temi ti jade ni akobi Iku Ijamofo, Lemikan l’oruko re n je. Looto, o ku saaju baba re. Sugbon, o lowo pupo nigba aye re. Itan so pe, nigba ti baba re, Iku Ijamofo rii pe eeyan nla ni Lemikan, omo re yii, loju aye re lo ti fun un ni gbogbo nnkan to to si i ninu ogun re, ko to ku.

Lemikan naa gbiyanju, iyawo mokanlelogbon lo ni. O si bi opolopo omo.

Alariya Oodua – E seun, Kabiyesi. Bawo abi ilana won ni won fi n j’oba niluu Igodan Lisa?

Kabiyesi – Emi ni oba eleekeji ti won maa je niluu Igodan Lisa. Eni to je oba akoko, Oba Paul Abiodun Akinsola ko j’oba nibere pepe. Oye Lisa ni won je. Sugbon, nigba ti ase ati onte ijoba de pe ki won so won di oba. Won so won di oba.

Odun metadinlogun ni won lo nipo. Sugbon, awon odun ti won ti lo seyin yen ko si ninu iwe ijoba. Idi ti won fi yan won l’oba nigba yen ni pawon afobaje lo ni ki won fi won j’oba. Leyin ti won si ku, ti won se oku won tan ninu osu kin-in-ni odun 2021. Won kede pe, ipo yen sofo.

Ohun kan to jo emi loju ni pe, saaji asiko yen, lati nnkan bi odun merin ni won ti maa n so fun mi pe oba ni mi. Odun 2016 ni mo pada de lati ile America at’igba yen ni Olorun ti fi han awon kan pe won ri ade lori mi. Ti mo ba lo si soosi kan lati lo josin, ti elemi ba wa nibe, yoo pe mi jade..

Lojo kan ninu osu kin-in-ni odun to koja, mo wa laduugbo Amuloko niluu Ibadan. Baba mi ninu Oluwa kan lo n se akanse adura olojo jimoh meje. Boya jimoh kerin tabi ikarun-un ni mo tie lo, mi o le ranti mo. O bo sasiko ti won n se isinku oba wa yen lowo. Bi won se n seto yen lo, alufaa pase ki gbogbo awon to wa lowo eyin jade bo siwaju. Ti mo ba lo sawon eto bayen, owo eyin ni mo maa n jokoo si, ki n le raaye sadura daadaa. Bi mo se n jade bo siwaju, wolii yen ni “Mo ri ade ide lori arakunrin yii, irukere ati ileke pelu.”

O ni, se idile oba ni mo ti wa ni? Sugbon, nitori ti mi o kii fe gbo ise yen. Ki n to dahun, mo so ninu mi pe rara. Loju ese ni wolii yen so pe, “arakunrin yii si n paro fun mi ninu emi.” O ni ki n ri oun leyin eto.

Nigba ti mo yoju si i leyin eto, o so orisirisi oro. O salaye pe, ade ti oun ri lori mi lati orun ni. O beere pe, se enikeni ko so fun mi ri, mo si ni won ti maa n so fun mi. O ni, o di dandan ki de ade yen loju aye. Ki ayanmo ati akosile yen le wa simuse

O beere ohun ti won n se lowo niluu wa ba a se n soro yii. Mo ni won n se isinku Kabiyesi to gbe’se. O ni oun pelu ti rii. O wa gba mi nimoran lati pada siluu leyin ose kan ti won ba pari isinku yen, ki n si lo so fun eni to n dari ilu lasiko yii pe Olorun lo ran mi wa lati wa tun ilu Igodan Lisa se.

Nitori naa, leyin ose kan, mo lo ri Baba Lisa to n sakooso ilu. Mo si so fun un. O l’oun ti gbo, ka maa lo, ka pada wa lojo keji. Boya o fe lo beere si i ni o, emi o mo. Nigba to d’ojo keji, a pada lo ba a. O si ni oun ti gbo, sugbon ile kan ti baba mi n ko lowo, ti ko pari lati odun yii, ki n lo pari re na. O ni ise po fun mi lati se, bee si lawon atunse kan wa ti maa se. Ko si pe, ti won fi kede pe ipo yen ti sofo.

Bayii ni mo fi erongba mi han. Awon mefa mi-in naa so po wu awon, a si je meje.

Sugbon, nigba ta a nipenija oro aabo niluu. Won ni ki gbogbo wa mu egberun lona igba naira wa lati ran ilu lowo. Enikan ko san owo yen, o l’oun o lowo. Bayii la ku mefa. Meji lara wa lo je omo oba to gbe’se. Won ni baba won ti so, ko to ku pe t’oun ba ku tan, awon ni ko gba ipo yen. Pelu pe won mo pe idile merinlelogbon ni wa.

Yato sawon meji yii, awon meta to je agbaoye niluu naa lawon letoo sipo yen. Mesan-an lawon agbaoye to wa niluu, awon si ni afobaje. Nitori naa, emi nikan ni mi o kii sara won tele. Opo awon awuyewuye lo tie waye lori oro yen. Awon kan ni, mi o kii se oloye tele, sugbon a je ko ye won pee mi ni mo kunju osunwon julo laarin gbogbo awa ta a dupo yen. Nitori, eni to ba maa j’oba, ko gbodo je oloye kan tele.

Nnkan mi-in ti won tun so ni pe, mo si ni obi laye. Nitori ti, baba ati mama si wa. Awon kan ni eni tawon obi re ba si wa laye ko le j’oba. Ninu molebi temi, awa meji la jade lati dupo yii. Nibe lawon molebi kan tun ti n so pe, enikan gbodo ju’wo sile fun enikan ni ati pe omode lo gbodoju’wo sile fun agbalagba. Nitori naa, emi ni ki n fipo yen sile fun enikeji, nitori to ju mi lo.

Mo si kuku ti so fun won tele pe, mi o setan lati dupo pelu enikeni, sugbon Olorun lo ran mi lati wa j’oba niluu yii. Nitori naa, tawon ilu ba fe mi, ti won nigbagbo ninu oro Olorun. Deedee ni.

E ma gbagbe pe, idile temi ni akobi ninu omo Iku Ijamofo. Nitori naa, a gbodo rii daju p’awa la j’oba yii. Ka si wa maa yii po laarin ara wa. Bi bee ko, ta a ba ti lo so anfaani yii nu, a le ma rii mo ni ogorun-un to n bo.

Bayii ni ilu gbe igbimo aluyewo kale. Awon igbimo yen ninu ipade won kan tie ni otosi kii j’oba, won l’eni to ba fe j’oba gbodo lo gbe eru ilu. Nitori naa, won ni ki gbogbo wa lo san milionu meji enikookan ati p’owo yen ko see gba pada. Awa kan faramo on, awon kan o faramo on. Ohun to tun wa le nibe ni pa a ti gbodo sanwo yen ko to d’ojo ti won maa se ayewo fun wa..

Wolii kan si ti jise fun mi ri pe, isegun kan to wa fun mi ni pe, gbogbo nnkan tiluu ba ni ka se. Ki n rii daju p’emi l’eni akoko ti yoo maa se e. Awa meta ni won pe fun iforowero ati ayewo lojo kan. Emi si ni won koko pe wole. Wakati kan ataabo ni mo si lo niwaju won. Nitori tawon obi mi si wa laye, ara mi ni oju gbogbo eeyan wa. Enikan beere ibeere mejo lowo mi. Ohun kan ti mo se ni pe, mo farabale dahun awon ibeere won. Mi o si dide kuro niwaju won titi mo fi pari. E moa won ibeere to le mu k’eeyan binu, sugbon mo kora mi nijanu.

Leyin ayewo ati iforowero yen, mo pada siluu Eko. Nitori, nibe ni mo ti n ri toro-kobo mi, sugbon mo rii daju pe mo n wa larowoto nigba yoowu ti won ba nilo mi. Nigba ti esi jade, awa meji la yege, emi si l’eni akoko. Awa mejeeji la sanwo ti won beere. Ti kii ba sii se pe Olorun n fe mi nipo yii ni, a o le so ohun ti ko ba sele. Nitori, awon eeyan yii n s’oogun pupo. Laarin awa mefa, babalawo ni meta. Koda, eni to wa lat’inu molebi mi yen lo lo so fun enikeji pe ko lo gba owo re pada lowo awon igbimo yen. O nipo oba ko ye ko je tita. Niyen naa ba lo gba looya kan lati ba a gb’owo re pada. Nigba ti won beere boya emi naa fe gb’owo mi pada, mo ni mo ti fun ilu. Ki won lo lo o fun idagbasoke ilu.

Nigba ti mo so pe, mo ti fun ilu l’owo, awon eeyan patewo fun mi. Leyin naa ni won mu ojo fun idibo. Sugbon, ko to d’ojo yen, opo awon igbese aburu ni won n gbe. Eni to wa lati molebi mi yen gan tie lo fi ara re j’oba, ko to di p’awon ilu le e danu. Nitori, emi ni gbogbo ilu n fe nipo.

Alariya Oodua – Kabiyesi! Ki l’awon nnkan tee ti le se lara awon ileri te e se?

Kabiyesi – Ohun kan ti mo koko se, bi mo se depo ni lati maa lo ki gbogbo awon ijo Olorun to wa niluu lojo sannde kookan, ki n si mo ki nipenija ti won ni. Leyin eyi, awon osise ile iwosan alaboode to wa niluu wa ki mi. Won ni ko si geeti lenu ona won, mo si seleri lati se e fun won. Maa gbe e fun won lose to n bo lagbara Olorun, nitori ti won ti n sise lori re lo. Yato seyii, awon osise ile-eko girama wa nibi wa ki mi lanaa. Won salaye pe, awon orule won n jo. Nitori naa, mo beere awon igbimo ile-eko won, nitori ti mi o fe maa se nnkan kan lai je k’awon eeyan mi maa mo sii. Mo ni ki won fun mi ni bi maa se r’awon igbimo yen ba soro lati mo nnkan ta a ba le se fun won. Nitori naa, a ni ero fun awon naa.

Ohun mi-in ti mo tun n se ni pe, mo sagbekale igbimo eleto-aabo. Nitori ta a nipenija eto aabo. Awon ole maa n way o awon akekoo to n gbe niluu lenu pupo. Lat’igba ti mo ti depo awon baba nla mi yi, mo sakiyesi pawon akekoo ko fe maa gbe niluu, nitori tawon kan n wa kolu won. Won n ji won l’eru ko lo, won si n fipa b’awon obinrin won lasepo. Nitori naa, mo gba awon osise eleto-aabo mejo lowo ara mi. Laarin emi ati olori odo ilu, mo so fun un pe maa sanwo awon osise eleto-aabo yen l’apo mi fun osu meta akoko. Nitori naa, owo osu enikookan won je egberun lona ogun naira. Lori eleyii, ko siranlowo kankan lati ibi kan kan lasiko yii. Laarin emi ati Olorun nikan ni, a fi ta aba r’eni to fife han si nnkan to wa nile yii. Mo si le gbe e fun osu meta na.

Leyin eyi, a n sise lori okan-o-jokan awon igbimo fun ise idagbasoke ilu.

Alariya Oodua – Gege bi kristeni, ki lajosepo to wa laarin eyin atawon elesin to ku, paapaa awon musulumi ati elesin ibile?

Kabiyesi – E seun. Gege bi oba niluu, looto awon eeyan maa n so pe oba o kii l’esin. Iro ni! Oba l’esin, sugbon gbogbo esin ni ti oba. E je ki n bere bayii. Mo n b’awon elesin ibile soro lojo wo pe, mi o wa lati pa esin won run. Sugbon, ki won fun mi laaye lati jise ti Olorun ran mi.

Mo ni ti kii ba tii se ilana mi, mi o nii di won lowo. Sugbon, ki awon naa ma di mi lowo ise ti Olorun fi ran mi. Ki won je ki alaafia j’oba niluu.

Won mo pe, mi o kii je obi, mi o kii mu oti, mi o de kii j’eran. Mo so fun lati ibere pepe pe, mi o kii se gbogbo nnkan wonyi. Ko ma wa je pe, nigba to depo tan lo to so fun wa p’oun o kii se nnkan kan. Mi o kii j’eran ewure, koda o loju iru adie ti mo maa n je.

Sugbon, mi o nii tori pe, mi o kii se nnkan wonyi. Ta a ba r’eni to se, to si je nnkan yii ni ohun itanran re. Ki won gba, ki won fun awon to maa n je e. Mi o wa sibi lati pa asa ati ise ti won ti n se run. Kii se nnkan ta a ran mi wa se niyen.

Iru odun “Ere” bayii, maa darapo mo won lati se e. Odun “Ijesu”, maa darapo mo won lati se e. Nigba ti akoko re ba to.

Ni t’awon musulumi, won wa ki mi nibi ni bi ojo meta seyin. Won si sadura. Emi naa gba won towo-tese, mo si sadura pe won yoo mo asiko ti oba je yii si rere. Mo so fun won pe, mo l’awon musulumu l’oree to po niluu Eko ti mo ti wa. Okan tie wa, to je Alaaji. T’awon eeyan ba ri okan ninu wa, ibeere ti won o koko beere to ba je emi ni won ri ni “Pasito, Alaaji n ko? To ba si je oun naa ni won koko ri, won a ni “Alaaji, Pasito n ko? Nitori idi eyi, a sun mora wa gan ni. Esin tie kii se temi, esin temi naa kii se tie. Mo so fun won pe, mo l’awon ore musulumi to po, ta a jo n se daadaa.

Mo gba won niyanju lati lo wa ile, ti won yoo fi ko mosalasi. Nitori, wiwa mi yii, nigba ti yoo ba fi to odun marun-un sasiko yii, eni to ba maa ra ile niluu yii yoo mura o. Ohun ti Oloun fi han mi niyen pe, ile kiko ti yoo sele laarin asiko yii s’odun to n bo yoo lagbara pupo.

Logan ti mo si d’ori apere yii, awon molebi bii merin to wa loke okun lo ti ni, ni bayii ti oba ti je yii, awon fe wa sile lati wa ko’le. Awon meji ninu won ti ra ile pulooti meji-meji, a si n b’awon to ku wa tiwon lowo.

Awon molebi kan wa, ti won ti kuro niluu yii lati nnkan bi ogorun-un odun. Lasiko ta a n mura igbade mi, won ni ti Olorun ba gbe mi depo, awon n pada bo siluu yii. Ko din ni eni meedogun to wa ninu molebi yii. E si mo pe, bi idagbasoke ba se n po si niluu, ni iye ti won n ta ile yoo maa goke sii. Ti ibeere fun oja kan ba se n po sii, bee ni owo re yoo maa won sii. Nitori naa, awon musulumi ti mo ni ki won lo wa ile yen, nigba to ba to akoko, maa mo nnkan ti maa se lati ran won lowo. Won tie fun mi ni ebun foto kan, ti won ko keu si.    

Alariya Oodua – E seun, Kabiyesi. Ki le le so nipa Ambassador Ibironke Oluwayemisi Onitiju?

Kabiyesi – Okan lara awon arabinrin wa ni. Oun ni Yeye Jima ilu Igodan Lisa. Omo wa ta a le fi yangan ni. Omo wa, to rin irin-ajo, sugbon ti ko gbagbe ile ni. Omo wa, to l’aanu si gbogbo eeyan ni.

Ona ti mo gba mo on ati awon iroyin ti mo gbo nipa re fi han pe kii se po n seranwo f’awon omo ilu yii nikan. T’eeyan ba ti so ede Ikale, o ti gbagbo p’eeyan oun ni.

Adura mi fun un ni pe, aabo Olorun yoo maa wa lori re. Ki Olorun ma fi sile. Ise ti Olorun fi ran an, ki Olorun fun un ni oore-ofe lati le je e nirorun. Ki ile ati ona re o ma baje.

Mo so fun un pe, ni bayii ta a mora. O o ri awon nnkan ti Olorun yoo maa se laye re. Mo sadura fun un pe, gbogbo nnkan rere to beere fun ati eyi ti ko beere fun ni Olorun yoo se fun un. Nitori to nifee ilu re pupo.

A sun mora pupo. Gbogbo igba la maa n soro, a o si le se ose kan, ka ma soro.

Alariya Oodua – Gbogbo wa la mo pe, t’eni meji ba n ja si nnkan, enikan ni yoo ja mo lowo. Ni bayii, to je eyin lo ja mo lowo. Ki l’awon igbese te e ti n gbe lati fa oju awon te e jo dupo mora?

Kabiyesi – A o tii gbe igbese kankan to po lori eyi, sugbon funra temi, mo ti pe okan lara won. A si lo to wakati meji ta a fi soro. O so fun mi pe, ero awon ni pe okan lara won ni yoo jawe olubori, Sugbon, emi ti mo kan wa lati ibi ti enikeni ko mo lo wa bori. Mo so fun un pe, o ye ko mo pe Olorun lo ran mi wa.

Mo ni, ohun to ye ko wa l’okan gbogbo wa ni ife ilu yii. Mo ni, kii se gbogbo awa mefeefa to dupo naa ni yoo depo ohun l’eekan naa. Mo ni, to ba je oun naa l’awon ilu fe, maa satileyin fun un ni.

Eyi to wa lati inu molebi mi ni tie, gbe gomina, alakooso eto idajo, ofiisi to n ri soro oye jije, alaga ijoba ibile wa ati emi pelu, awa maraarun lo sile-ejo giga niluu Okitipupa. Ejo yii si wa nibe.

Okan lara awon merin to ku naa ko iwe esun kan mo mi. Sugbon, omo wa kan wa to n gbe niluu Ibadan, Dokita Oyedele, o sun mo gomina pupo. Oun lo ni ki n ma je ki oro iwe esun yen da iporuru okan fun mi. Mo wa so fun un pe, yoo wu mi ko je alaga igbimo ti yoo petu s’aawo laarin awa ta a jo dupo. Mo so fun un pe, ko wa awon eeyan merin mi-in ti won le jo sise po ninu igbimo yen.